Luku 5:27
Luke 5:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́hìn èyí, Jesu jáde lọ, ó sì rí agbowó òde kan tí à ń pè ní Lefi, ó jókòó sí ibi tí ó ti ń gba owó òde, Jesu sì wí fún un pé, “Tẹ̀lé mi,”
Luke 5:27 in English
Luke 5:27 · Berean Standard Bible
After this, Jesus went out and saw a tax collector named Levi sitting at the tax booth. “Follow Me,” He told him,
Context
25Ó sì dìde lọ́gán níwájú wọn, ó gbé ohun tí ó dùbúlẹ̀ lé, ó sì lọ sí ilé rẹ̀, ó yin Ọlọ́run lógo. 26Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, ẹ̀rù sì bà wọ́n, wọ́n ń wí pé, “Àwa rí ohun ìyanu lónìí.” 27Lẹ́hìn èyí, Jesu jáde lọ, ó sì rí agbowó òde kan tí à ń pè ní Lefi, ó jókòó sí ibi tí ó ti ń gba owó òde, Jesu sì wí fún un pé, “Tẹ̀lé mi,” 28Lefi sì fi ohun gbogbo sílẹ̀ ó sì ń tẹ̀lé e. 29Lefi sì ṣe àsè ńlá kan fún Jesu ní ilé rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti àwọn mìíràn sì ń jẹun pẹ̀lú wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.