Native Bible

Luke 5:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ sí í gbèrò wí pé, “Ta ni eléyìí tí ń sọ ọ̀rọ̀-òdì? Ta ni ó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí kò ṣe Ọlọ́run nìkan ṣoṣo.”

Luke 5:21 in English

Luke 5:21 · Berean Standard Bible

But the scribes and Pharisees began thinking to themselves, “Who is this man who speaks blasphemy? Who can forgive sins but God alone?”

Context

19Nígbà tí wọn kò sì rí ọ̀nà tí wọn ìbá fi gbé e wọlé nítorí ìjọ ènìyàn, wọ́n gbé e gun òkè àjà ilé lọ, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ sí àárín èrò ti òun ti àkéte rẹ̀ níwájú Jesu. 20Nígbà tí ó sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí pé, “Ọkùnrin yìí, a darí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.” 21Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ sí í gbèrò wí pé, “Ta ni eléyìí tí ń sọ ọ̀rọ̀-òdì? Ta ni ó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí kò ṣe Ọlọ́run nìkan ṣoṣo.” 22Jesu sì mọ èrò inú wọn, ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ fi ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín? 23Èwo ni ó yá jù: láti wí pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ tàbí láti wí pé, ‘Dìde kí ìwọ sì máa rìn’?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.