Luku 5:15
Luke 5:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n òkìkí rẹ̀ ń kàn kálẹ̀: tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì jùmọ̀ pàdé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti gba ìwòsàn lọ́dọ̀ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àìlera wọn.
Luke 5:15 in English
Luke 5:15 · Berean Standard Bible
But the news about Jesus spread all the more, and great crowds came to hear Him and to be healed of their sicknesses.
Context
13Jesu sì na ọwọ́ rẹ̀, ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́!” Lójúkan náà ẹ̀tẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ. 14Ó sì kìlọ̀ fún u pé, “Kí ó má ṣe sọ fún ẹnìkan: ṣùgbọ́n kí ó lọ, kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn fún àlùfáà, kí ó sì ta ọrẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ gẹ́gẹ́ bi ẹ̀rí fun wọn.” 15Ṣùgbọ́n òkìkí rẹ̀ ń kàn kálẹ̀: tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì jùmọ̀ pàdé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti gba ìwòsàn lọ́dọ̀ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àìlera wọn. 16Ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà ni Jesu a máa yẹra kúrò si ibi ìdákẹ́rọ́rọ́, òun á sì máa dá wà láti gbàdúrà. 17Ní ọjọ́ kan, bí ó sì ti ń kọ́ni, àwọn Farisi àti àwọn amòfin jókòó pẹ̀lú rẹ̀, àwọn tí ó ti àwọn ìletò Galili gbogbo, àti Judea, àti Jerusalẹmu wá: agbára Olúwa sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ láti mú wọn láradá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.