Luku 5:12
Luke 5:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì ṣe, nígbà tí Jesu wọ ọ̀kan nínú àwọn ìlú náà, kíyèsi i, ọkùnrin kan tí ẹ̀tẹ̀ bò wa síbẹ̀: nígbà tí ó rí Jesu, ó wólẹ̀, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, wí pé, “Olúwa, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè sọ mí di mímọ́.”
Luke 5:12 in English
Luke 5:12 · Berean Standard Bible
While Jesus was in one of the towns, a man came along who was covered with leprosy.* When he saw Jesus, he fell facedown and begged Him, “Lord, if You are willing, You can make me clean.”
Context
10bẹ́ẹ̀ ni Jakọbu àti Johanu àwọn ọmọ Sebede, tí ń ṣe alábákẹ́gbẹ́ Simoni.
Jesu sì wí fún Simoni pé, “Má bẹ̀rù; láti ìsinsin yìí lọ ìwọ ó máa mú ènìyàn.” 11Nígbà tí wọ́n sì ti mú ọkọ̀ wọn dé ilẹ̀, wọ́n fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lọ. 12Ó sì ṣe, nígbà tí Jesu wọ ọ̀kan nínú àwọn ìlú náà, kíyèsi i, ọkùnrin kan tí ẹ̀tẹ̀ bò wa síbẹ̀: nígbà tí ó rí Jesu, ó wólẹ̀, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, wí pé, “Olúwa, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè sọ mí di mímọ́.” 13Jesu sì na ọwọ́ rẹ̀, ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́!” Lójúkan náà ẹ̀tẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ. 14Ó sì kìlọ̀ fún u pé, “Kí ó má ṣe sọ fún ẹnìkan: ṣùgbọ́n kí ó lọ, kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn fún àlùfáà, kí ó sì ta ọrẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ gẹ́gẹ́ bi ẹ̀rí fun wọn.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.