Luku 24:17
Luke 24:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì bi wọ́n pé, “Ọ̀rọ̀ kín ni ẹ̀yin ń bá ara yín sọ, bí ẹ̀yin ti ń rìn?” Wọ́n sì dúró jẹ́, wọ́n fajúro.
Luke 24:17 in English
Luke 24:17 · Berean Standard Bible
He asked them, “What are you discussing so intently as you walk along?” They stood still, with sadness on their faces.
Context
15Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń bá ara wọn jíròrò, Jesu tìkára rẹ̀ súnmọ́ wọn, ó sì ń bá wọn rìn lọ. 16Ṣùgbọ́n a rú wọn lójú, kí wọn má le mọ̀ ọ́n. 17Ó sì bi wọ́n pé, “Ọ̀rọ̀ kín ni ẹ̀yin ń bá ara yín sọ, bí ẹ̀yin ti ń rìn?”
Wọ́n sì dúró jẹ́, wọ́n fajúro. 18Ọ̀kan nínú wọn, tí a ń pè ní Kileopa, sì dáhùn wí fún un pé, “Àlejò sá à ni ìwọ ní Jerusalẹmu, tí ìwọ kò sì mọ ohun tí ó ṣẹ̀ níbẹ̀ ní ọjọ́ wọ̀nyí?” 19Ó sì bi wọ́n pé, “Kín ni?”
Wọ́n sì wí fún un pé, “Ní ti Jesu ti Nasareti, ẹni tí ó jẹ́ wòlíì, tí ó pọ̀ ní ìṣe àti ní ọrọ̀ níwájú Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.