Native Bible

Luke 22:52 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jesu wí fún àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili, àti àwọn alàgbà, tí wọ́n jáde tọ̀ ọ́ wá pé, “Ẹ̀yin ha jáde wá pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ bí ẹni tọ ọlọ́ṣà wá?

Luke 22:52 in English

Luke 22:52 · Berean Standard Bible

Then Jesus said to the chief priests, temple officers, and elders who had come for Him, “Have you come out with swords and clubs as you would against an outlaw?

Context

50Ọ̀kan nínú wọn sì fi idà ṣá ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé etí ọ̀tún rẹ̀ sọnù. 51Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn ó wí pé, “Ko gbọdọ̀ ṣe èyí mọ.” Ó sì fi ọwọ́ tọ́ ọ ní etí, ó sì wò ó sàn. 52Jesu wí fún àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili, àti àwọn alàgbà, tí wọ́n jáde tọ̀ ọ́ wá pé, “Ẹ̀yin ha jáde wá pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ bí ẹni tọ ọlọ́ṣà wá? 53Nígbà tí èmi wà pẹ̀lú yín lójoojúmọ́ ní tẹmpili, ẹ̀yin kò na ọwọ́ mú mi, ṣùgbọ́n àkókò tiyín ni èyí, àti agbára òkùnkùn n jẹ ọba.” 54Wọ́n sì gbá a mú, wọ́n sì fà á lọ, wọ́n sì mú un wá sí ilé olórí àlùfáà. Ṣùgbọ́n Peteru tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní òkèrè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.