Native Bible

Luke 22:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, ó lọ láti bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ gbèrò pọ̀, bí òun yóò tí fi í lé wọn lọ́wọ́.

Luke 22:4 in English

Luke 22:4 · Berean Standard Bible

And Judas went to discuss with the chief priests and temple officers how he might betray Jesus to them.

Context

2Àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà tí wọn ìbá gbà pa á; nítorí tí wọn ń bẹ̀rù àwọn ènìyàn. 3Satani sì wọ inú Judasi, tí à ń pè ní Iskariotu, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá. 4Ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, ó lọ láti bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ gbèrò pọ̀, bí òun yóò tí fi í lé wọn lọ́wọ́. 5Wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì bá a dá májẹ̀mú láti fún un ní owó. 6Ó sì gbà; ó sì ń wá àkókò tí ó wọ̀, láti fi í lé wọn lọ́wọ́ láìsí ariwo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.