Luku 22:10
Luke 22:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì wí fún wọn pé, “Kíyèsi i, nígbà tí ẹ̀yin bá ń wọ ìlú lọ, ọkùnrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóò pàdé yín, ẹ bá a lọ sí ilé tí ó bá wọ̀,
Luke 22:10 in English
Luke 22:10 · Berean Standard Bible
He answered, “When you enter the city, a man carrying a jug of water will meet you. Follow him to the house he enters,
Context
8Ó sì rán Peteru àti Johanu, wí pé, “Ẹ lọ pèsè ìrékọjá fún wa, kí àwa ó jẹ.” 9Wọ́n sì wí fún un pé, “Níbo ni ìwọ ń fẹ́ kí á pèsè sílẹ̀?” 10Ó sì wí fún wọn pé, “Kíyèsi i, nígbà tí ẹ̀yin bá ń wọ ìlú lọ, ọkùnrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóò pàdé yín, ẹ bá a lọ sí ilé tí ó bá wọ̀, 11kí ẹ sì wí fún baálé ilé náà pé, ‘Olùkọ́ wí fún ọ pé, níbo ni gbàngàn àpèjẹ náà gbé wà, níbi tí èmi ó gbé jẹ ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’ 12Òun ó sì fi gbàngàn ńlá kan lókè ilé hàn yín, tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin pèsè sílẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.