Native Bible

Luke 21:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àyà àwọn ènìyàn yóò máa já fún ìbẹ̀rù, àti ìrètí nǹkan wọ̀nyí tí ń bọ̀ sórí ayé: nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì tìtì.

Luke 21:26 in English

Luke 21:26 · Berean Standard Bible

Men will faint from fear and anxiety over what is coming upon the earth, for the powers of the heavens will be shaken.

Context

24Wọn ó sì ti ojú idà ṣubú, a ó sì dìwọ́n ní ìgbèkùn lọ sí orílẹ̀-èdè gbogbo; Jerusalẹmu yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aláìkọlà, títí àkókò àwọn aláìkọlà yóò fi kún. 25“Àmì yóò sì wà ní oorun, àti ní òṣùpá, àti ní ìràwọ̀; àti lórí ilẹ̀ ayé ìdààmú fún àwọn orílẹ̀-èdè nínú ìpayà híhó Òkun àti ìgbì omi. 26Àyà àwọn ènìyàn yóò máa já fún ìbẹ̀rù, àti ìrètí nǹkan wọ̀nyí tí ń bọ̀ sórí ayé: nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì tìtì. 27Nígbà náà ni wọn ó sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò máa bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. 28Ṣùgbọ́n nígbà tí nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ, ǹjẹ́ kí ẹ wo òkè, kí ẹ sì gbé orí yín sókè; nítorí ìdáǹdè yín kù sí dẹ̀dẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.