Native Bible

Luke 21:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ṣùgbọ́n ṣáájú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọn ó nawọ́ mú yín, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí yín, wọn ó mú yín lọ sí Sinagọgu, àti sínú túbú, wọn ó mú yín lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba àti àwọn ìjòyè nítorí orúkọ mi.

Luke 21:12 in English

Luke 21:12 · Berean Standard Bible

But before all this, they will seize you and persecute you. On account of My name they will deliver you to the synagogues and prisons, and they will bring you before kings and governors.

Context

10Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba. 11Ilẹ̀-rírì ńlá yóò sì wà káàkiri, àti ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn; ohun ẹ̀rù, àti àmì ńlá yóò sì ti ọ̀run wá. 12“Ṣùgbọ́n ṣáájú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọn ó nawọ́ mú yín, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí yín, wọn ó mú yín lọ sí Sinagọgu, àti sínú túbú, wọn ó mú yín lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba àti àwọn ìjòyè nítorí orúkọ mi. 13Ẹ o si jẹ́rìí nípa mi. 14Nítorí náà ẹ pinnu rẹ̀ ní ọkàn yín pé ẹ ko ronú ṣáájú, bí ẹ ó ti dáhùn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.