Native Bible

Luke 20:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì tún rán ẹ̀kẹta: wọ́n sì sá a lọ́gbẹ́ pẹ̀lú, wọ́n sì tì í jáde.

Luke 20:12 in English

Luke 20:12 · Berean Standard Bible

Then he sent a third, but they wounded him and threw him out.

Context

10Nígbà tí ó sì tó àkókò, ó rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ kan sí àwọn olùṣọ́gbà náà, kí wọn lè fún un nínú èso ọgbà àjàrà náà, ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú lù ú, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo. 11Ó sì tún rán ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn, wọ́n sì lù ú pẹ̀lú, wọ́n sì jẹ ẹ́ ní yà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo. 12Ó sì tún rán ẹ̀kẹta: wọ́n sì sá a lọ́gbẹ́ pẹ̀lú, wọ́n sì tì í jáde. 13“Nígbà náà ni Olúwa ọgbà àjàrà wí pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Èmi ó rán ọmọ mi àyànfẹ́ lọ: bóyá nígbà tí wọ́n bá rí i, wọn yóò bu ọlá fún un.’ 14“Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn alágbàtọ́jú náà rí i, wọ́n bá ara wọn gbèrò pé, ‘Èyí ni àrólé; ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí ogún rẹ̀ lè jẹ́ ti wa.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.