Native Bible

Luke 2:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Angẹli Olúwa sì yọ sí wọn, ògo Olúwa sì ràn yí wọn ká, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.

Luke 2:9 in English

Luke 2:9 · Berean Standard Bible

Just then an angel of the Lord stood before them, and the glory of the Lord shone around them, and they were terrified.

Context

7Ó sì bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkùnrin, ó sì fi ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran; nítorí tí ààyè kò sí fún wọn nínú ilé èrò. 8Àwọn olùṣọ́-àgùntàn ń bẹ tí wọ́n ń gbé ní ìlú náà, wọ́n ń ṣọ́ agbo àgùntàn wọn ní òru ní pápá tí wọ́n ń gbé. 9Angẹli Olúwa sì yọ sí wọn, ògo Olúwa sì ràn yí wọn ká, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. 10Angẹli náà sì wí fún wọn pé, “Má bẹ̀rù: sá wò ó, mo mú ìyìnrere ayọ̀ ńlá fún yín wá, tí yóò ṣe ti ènìyàn gbogbo. 11Nítorí a ti bí Olùgbàlà fún yín lónìí ní ìlú Dafidi, tí í ṣe Kristi Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.