Luku 2:23
Luke 2:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
(bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Olúwa pé, “Gbogbo ọmọ ọkùnrin tí ó ṣe àkọ́bí, òun ni a ó pè ní mímọ́ fún Olúwa”),
Luke 2:23 in English
Luke 2:23 · Berean Standard Bible
(as it is written in the Law of the Lord: “Every firstborn male shall be consecrated to the Lord”*),
Context
21Nígbà tí ọjọ́ mẹ́jọ sì pé láti kọ ọmọ náà nílà, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu, bí a ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ angẹli náà wá kí á tó lóyún rẹ̀. 22Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nù Maria sì pé gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, Josẹfu àti Maria gbé Jesu wá sí Jerusalẹmu láti fi í fún Olúwa 23(bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Olúwa pé, “Gbogbo ọmọ ọkùnrin tí ó ṣe àkọ́bí, òun ni a ó pè ní mímọ́ fún Olúwa”), 24àti láti rú ẹbọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí nínú òfin Olúwa: “Àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì.” 25Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan wà ní Jerusalẹmu, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Simeoni; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́ àti olùfọkànsìn, ó ń retí ìtùnú Israẹli, Ẹ̀mí mímọ́ sì bà lé e.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.