Native Bible

Luke 19:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ẹnikẹ́ni bá sì bi yín pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tú u?’ Kí ẹ̀yin wí báyìí pé, ‘Olúwa ń fẹ́ lò ó.’ ”

Luke 19:31 in English

Luke 19:31 · Berean Standard Bible

If anyone asks, ‘Why are you untying it?’ tell him, ‘The Lord needs it.’”

Context

29Ó sì ṣe, nígbà tí ó súnmọ́ Betfage àti Betani ní òkè tí a ń pè ní òkè olifi, ó rán àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 30Wí pé, “Ẹ lọ sí ìletò tí ó kọjú sí yín; nígbà tí ẹ̀yin bá wọ̀ ọ́ lọ, ẹ̀yin ó rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí a so, tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí, ẹ tú u, kí ẹ sì fà á wá. 31Bí ẹnikẹ́ni bá sì bi yín pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tú u?’ Kí ẹ̀yin wí báyìí pé, ‘Olúwa ń fẹ́ lò ó.’ ” 32Àwọn tí a rán sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó ti wí fún wọn. 33Bí wọ́n sì ti ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn Olúwa rẹ̀ bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.