Native Bible

Luke 17:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo wí fún yín, ní òru ọjọ́ náà, ènìyàn méjì yóò wà lórí àkéte kan; a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀.

Luke 17:34 in English

Luke 17:34 · Berean Standard Bible

I tell you, on that night two people will be in one bed: One will be taken and the other left.

Context

32Ẹ rántí aya Lọti. 33Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wá àti gba ẹ̀mí rẹ̀ là yóò sọ ọ́ nù; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì sọ ọ́ nù yóò gbà á là. 34Mo wí fún yín, ní òru ọjọ́ náà, ènìyàn méjì yóò wà lórí àkéte kan; a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀. 35Ènìyàn méjì yóò sì máa lọ ọlọ pọ̀; a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀.”* 37Wọ́n sì dá a lóhùn, wọ́n bi í pé, “Níbo, Olúwa?” Ó sì wí fún wọn pé, “Níbi tí òkú bá gbé wà, níbẹ̀ pẹ̀lú ni igún ìkójọpọ̀ sí.” 17.35 Àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́ kan se àfikún ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀. 36Àwọn ọkùnrin méjì yóò máa ṣiṣẹ́ nínú oko, a o mú ẹnìkan, a ó sì fi ẹni kejì sílẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.