Native Bible

Luke 17:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ máa kíyèsára yín. “Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀, bá a wí; bí ó bá sì ronúpìwàdà, dáríjì ín.

Luke 17:3 in English

Luke 17:3 · Berean Standard Bible

Watch yourselves. If your brother sins, rebuke him; and if he repents, forgive him.

Context

1Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Kò le ṣe kí ohun ìkọ̀sẹ̀ máa wa, ṣùgbọ́n ègbé ni fún ẹni tí ó ti ipasẹ̀ rẹ̀ dé. 2Ìbá sàn fún un kí a so ọlọ mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì gbé e jù sínú Òkun, ju kí ó mú ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kọsẹ̀. 3Ẹ máa kíyèsára yín. “Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀, bá a wí; bí ó bá sì ronúpìwàdà, dáríjì ín. 4Bí ó bá sì ṣẹ̀ ọ́ ní igba méje ní òòjọ́, tí ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ìgbà méje ní òòjọ́ pé, ‘Mo ronúpìwàdà,’ dáríjì ín.” 5Àwọn aposteli sì wí fún Olúwa pé, “Bù sí ìgbàgbọ́ wa.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.