Native Bible

Luke 16:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ó sì wí pé, ‘Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) òsùwọ̀n òróró.’ “Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, sì jókòó nísinsin yìí, kí o sì kọ àádọ́ta lé ní irinwó (450).’

Luke 16:6 in English

Luke 16:6 · Berean Standard Bible

‘A hundred measures of olive oil,’* he answered. ‘Take your bill,’ said the manager. ‘Sit down quickly, and write fifty.’

Context

4Mo mọ èyí tí èmi yóò ṣe, nígbà tí a bá mú mi kúrò níbi iṣẹ́ ìríjú, kí àwọn ènìyàn le gbà mí sínú ilé wọn.’ 5“Ó sì pe àwọn ajigbèsè olúwa rẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún èkínní pé, ‘Èló ni ìwọ jẹ olúwa mi?’ 6“Ó sì wí pé, ‘Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) òsùwọ̀n òróró.’ “Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, sì jókòó nísinsin yìí, kí o sì kọ àádọ́ta lé ní irinwó (450).’ 7“Nígbà náà ni ó sì bi ẹnìkejì pé, ‘Èló ni ìwọ jẹ?’ “Òun sì wí pé, ‘Ẹgbẹ̀rún (1,000) òsùwọ̀n alikama.’ “Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, kí o sì kọ ẹgbẹ̀rin (800).’ 8“Olúwa rẹ̀ sì yin aláìṣòótọ́ ìríjú náà, nítorí tí ó fi ọgbọ́n ṣe é, àwọn ọmọ ayé yìí sá à gbọ́n ní ìran wọn ju àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.