Native Bible

Luke 16:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Òun a sì máa fẹ́ kí a fi èérún tí ó ti orí tábìlì ọlọ́rọ̀ bọ́ sílẹ̀ bọ́ òun, àwọn ajá sì wá, wọ́n sì fá a ní ooju lá.

Luke 16:21 in English

Luke 16:21 · Berean Standard Bible

and longing to be fed with the crumbs that fell from the rich man’s table. Even the dogs came and licked his sores.

Context

19“Ǹjẹ́ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ń wọ aṣọ elése àlùkò àti aṣọ àlà dáradára, a sì máa jẹ dídùndídùn lójoojúmọ́. 20Alágbe kan sì wà tí à ń pè ní Lasaru, tí wọ́n máa ń gbé wá kalẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà ilé rẹ̀, ó kún fún ooju, 21Òun a sì máa fẹ́ kí a fi èérún tí ó ti orí tábìlì ọlọ́rọ̀ bọ́ sílẹ̀ bọ́ òun, àwọn ajá sì wá, wọ́n sì fá a ní ooju lá. 22“Ó sì ṣe, alágbe kú, a sì ti ọwọ́ àwọn angẹli gbé e lọ sí oókan àyà Abrahamu: ọlọ́rọ̀ náà sì kú pẹ̀lú, a sì sin ín; 23Ní ipò òkú ni ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ń bẹ nínú ìjìyà oró, ó sì rí Abrahamu ní òkèrè, àti Lasaru ní oókan àyà rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.