Luku 16:2
Luke 16:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ó sì pè é, ó wí fún un pé, ‘Èéṣe tí èmi fi ń gbọ́ èyí sí ọ? Ṣírò iṣẹ́ ìríjú rẹ; nítorí ìwọ kò lè ṣe ìríjú mi mọ́.’
Luke 16:2 in English
Luke 16:2 · Berean Standard Bible
So he called him in to ask, ‘What is this I hear about you? Turn in an account of your management, for you cannot be manager any longer.’
Context
1Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pẹ̀lú pé, “Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ní ìríjú kan; òun náà ni wọ́n fi sùn ún pé, ó ti ń fi ohun ìní rẹ̀ ṣòfò. 2Nígbà tí ó sì pè é, ó wí fún un pé, ‘Èéṣe tí èmi fi ń gbọ́ èyí sí ọ? Ṣírò iṣẹ́ ìríjú rẹ; nítorí ìwọ kò lè ṣe ìríjú mi mọ́.’ 3“Ìríjú náà sì wí nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Nítorí tí olúwa mi gba iṣẹ́ ìríjú lọ́wọ́ mi: èmi kò le ṣiṣẹ́ oko, bẹ́ẹ̀ ni ojú ń tì mí láti ṣagbe. 4Mo mọ èyí tí èmi yóò ṣe, nígbà tí a bá mú mi kúrò níbi iṣẹ́ ìríjú, kí àwọn ènìyàn le gbà mí sínú ilé wọn.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.