Luku 16:14
Luke 16:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn Farisi, tí wọ́n ní ojúkòkòrò sì gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì yọ ṣùtì sí i.
Luke 16:14 in English
Luke 16:14 · Berean Standard Bible
The Pharisees, who were lovers of money, heard all of this and were scoffing at Jesus.
Context
12Bí ẹ̀yin kò bá sì ti jẹ́ olóòtítọ́ nínú ohun tí í ṣe ti ẹlòmíràn, ta ni yóò fún yín ní ohun tí í ṣe ti ẹ̀yin tìkára yín? 13“Kò sì í ẹnìkan tí ó lè sin ọ̀gá méjì. Òun yóò yà kórìíra ọ̀kan tí yóò fẹ́ràn èkejì, tàbí kí ó fi ara mọ́ ọ̀kan kí ó sì yan èkejì ní ìpọ̀sí. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run àti owó papọ̀.” 14Àwọn Farisi, tí wọ́n ní ojúkòkòrò sì gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì yọ ṣùtì sí i. 15Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni àwọn tí ń dá àre fún ara yín níwájú ènìyàn; ṣùgbọ́n Ọlọ́run mọ ọkàn yín, nítorí ohun ti a gbéga lójú ènìyàn, ìríra ni níwájú Ọlọ́run. 16“Òfin àti àwọn wòlíì ń bẹ títí di ìgbà Johanu, Láti ìgbà náà wá ni a ti ń wàásù ìròyìn ayọ̀ ìjọba Ọlọ́run, olúkúlùkù sì ń fi ipá wọ inú rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.