Luku 16:11
Luke 16:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò bá ti jẹ́ olóòtítọ́ nínú ọrọ̀ ayé yìí, ta ni yóò fi ọ̀rọ̀ tòótọ́ fún yín?
Luke 16:11 in English
Luke 16:11 · Berean Standard Bible
So if you have not been faithful with worldly wealth, who will entrust you with true riches?
Context
9Èmi sì wí fún yín, ẹ fi ọrọ̀ ayé yìí yan ọ̀rẹ́ fún ara yín pé, nígbà tí o ba lọ, kí wọn kí ó le gbà yín sí ibùjókòó wọn títí ayé. 10“Ẹni tí ó bá ṣe olóòtítọ́ nínú ohun kínkínní, ó ṣe olóòtítọ́ ní púpọ̀ pẹ̀lú: ẹni tí ó bá sì ṣe aláìṣòótọ́ ní ohun kínkínní, ó ṣe aláìṣòótọ́ ní ohun púpọ̀ pẹ̀lú. 11Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò bá ti jẹ́ olóòtítọ́ nínú ọrọ̀ ayé yìí, ta ni yóò fi ọ̀rọ̀ tòótọ́ fún yín? 12Bí ẹ̀yin kò bá sì ti jẹ́ olóòtítọ́ nínú ohun tí í ṣe ti ẹlòmíràn, ta ni yóò fún yín ní ohun tí í ṣe ti ẹ̀yin tìkára yín? 13“Kò sì í ẹnìkan tí ó lè sin ọ̀gá méjì. Òun yóò yà kórìíra ọ̀kan tí yóò fẹ́ràn èkejì, tàbí kí ó fi ara mọ́ ọ̀kan kí ó sì yan èkejì ní ìpọ̀sí. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run àti owó papọ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.