Native Bible

Luke 14:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Èkejì sì wí pé, ‘Mo ra àjàgà màlúù márùn-ún, mo sì ń lọ wò wọ́n wò: mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’

Luke 14:19 in English

Luke 14:19 · Berean Standard Bible

Another said, ‘I have bought five yoke of oxen, and I am going to try them out. Please excuse me.’

Context

17Ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní wákàtí àsè alẹ́ náà láti sọ fún àwọn tí a ti pè pé, ‘Ẹ wá; nítorí ohun gbogbo ṣetán!’ 18“Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwáwí ohun kan. ‘Èkínní wí fún un pé, mo ra ilẹ̀ kan, mo sì fẹ́ lọ wò ó wò, mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’ 19“Èkejì sì wí pé, ‘Mo ra àjàgà màlúù márùn-ún, mo sì ń lọ wò wọ́n wò: mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’ 20“Ẹ̀kẹta sì wí pé, ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, nítorí náà ni èmi kò fi lè wá.’ 21“Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì padà dé, ó sọ nǹkan wọ̀nyí fún olúwa rẹ̀. Nígbà náà ni baálé ilé bínú, ó wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, ‘Jáde lọ sí ìgboro, àti sí òpópó ọ̀nà, kí o sì mú àwọn tálákà, àti àwọn amúnkùn ún, àti àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú wá sí ìhín yìí.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.