Luku 13:34
Luke 13:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìwọ tí o pa àwọn wòlíì, tí o sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí ọ pa; nígbà mélòó ni èmi ń fẹ́ ràgà bo àwọn ọmọ rẹ, bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í ràgà bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ apá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́!
Luke 13:34 in English
Luke 13:34 · Berean Standard Bible
O Jerusalem, Jerusalem, who kills the prophets and stones those sent to her, how often I have longed to gather your children together as a hen gathers her chicks under her wings, but you were unwilling!
Context
32Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ, kí ẹ̀yin sì sọ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà pé, ‘Kíyèsi i, èmi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, èmi ń ṣe ìmúláradá lónìí àti lọ́la, àti ní ọjọ́ mẹ́ta èmi ó ṣe àṣepé.’ 33Ṣùgbọ́n èmi kò jẹ́ má rìn lónìí, àti lọ́la, àti ní ọ̀túnla: dájúdájú wòlíì kan ki yóò ṣègbé lẹ́yìn odi Jerusalẹmu. 34“Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìwọ tí o pa àwọn wòlíì, tí o sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí ọ pa; nígbà mélòó ni èmi ń fẹ́ ràgà bo àwọn ọmọ rẹ, bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í ràgà bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ apá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́! 35Sá wò ó, a fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro. Lóòtítọ́ ni mo sì wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi títí yóò fi di àkókò tí ẹ̀yin ó wí pé, ‘Olùbùkún ni ẹni tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.