Luku 13:27
Luke 13:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Òun ó sì wí pé, ‘Èmi wí fún yín èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá; ẹ lọ kúrò lọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’
Luke 13:27 in English
Luke 13:27 · Berean Standard Bible
And he will answer, ‘I tell you, I do not know where you are from. Depart from me, all you evildoers.’
Context
25Nígbà tí baálé ilé bá dìde lẹ́ẹ̀kan fùú, tí ó bá sí ti ìlẹ̀kùn, ẹ̀yin ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dúró lóde, tí ẹ ó máa kan ìlẹ̀kùn, wí pé, ‘Olúwa, Olúwa, ṣí i fún wa!’
“Òun ó sì dáhùn wí fún yín pé, ‘Èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá.’ Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mọ̀ yín. 26“Nígbà náà ni ẹ̀yin ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, ‘Àwa ti jẹ, àwa sì ti mu níwájú rẹ, ìwọ sì kọ́ni ní ìgboro ìlú wa.’ 27“Òun ó sì wí pé, ‘Èmi wí fún yín èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá; ẹ lọ kúrò lọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’ 28“Níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò wà, nígbà tí ẹ̀yin ó rí Abrahamu, àti Isaaki, àti Jakọbu, àti gbogbo àwọn wòlíì, ní ìjọba Ọlọ́run, tí a ó sì ti ẹ̀yin sóde. 29Wọn ó sì ti ilẹ̀ ìlà-oòrùn, àti ìwọ̀-oòrùn wá, àti láti àríwá, àti gúúsù wá, wọn ó sì jókòó ní ìjọba Ọlọ́run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.