Native Bible

Luke 12:48 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n èyí tí kò mọ̀, tí ó ṣe ohun tí ó yẹ sí lílù, òun ni a ó lù níwọ̀n. Nítorí ẹnikẹ́ni tí a fún ní púpọ̀, lọ́dọ̀ rẹ̀ ni a ó gbé béèrè púpọ̀: lọ́dọ̀ ẹni tí a bá gbé fi púpọ̀ sí, lọ́dọ̀ rẹ ni a ó gbé béèrè sí i.

Luke 12:48 in English

Luke 12:48 · Berean Standard Bible

But the one who unknowingly does things worthy of punishment will be beaten with few blows. From everyone who has been given much, much will be required; and from him who has been entrusted with much, even more will be demanded.

Context

46Olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà yóò dé ní ọjọ́ tí kò retí rẹ̀, àti ní wákàtí tí kò dábàá, yóò sì jẹ ẹ́ ní yà gidigidi, yóò sì yan ipò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́. 47“Àti ọmọ ọ̀dọ̀ náà, tí ó mọ ìfẹ́ olúwa rẹ̀, tí kò sì múra sílẹ̀, tí kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, òun ni a ó nà púpọ̀. 48Ṣùgbọ́n èyí tí kò mọ̀, tí ó ṣe ohun tí ó yẹ sí lílù, òun ni a ó lù níwọ̀n. Nítorí ẹnikẹ́ni tí a fún ní púpọ̀, lọ́dọ̀ rẹ̀ ni a ó gbé béèrè púpọ̀: lọ́dọ̀ ẹni tí a bá gbé fi púpọ̀ sí, lọ́dọ̀ rẹ ni a ó gbé béèrè sí i. 49“Iná ni èmi wá láti sọ sí ayé; kín ni èmi sì ń fẹ́ bí kò ṣe kí iná náà ti jo! 50Ṣùgbọ́n èmi ní bamitiisi kan tí a ó fi bamitiisi mi; ara ti ń ni mí tó títí yóò fi parí!

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.