Luku 12:41
Luke 12:41 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Peteru sì wí pé, “Olúwa, ìwọ pa òwe yìí fún wa, tàbí fún gbogbo ènìyàn?”
Luke 12:41 in English
Luke 12:41 · Berean Standard Bible
“Lord,” said Peter, “are You addressing this parable to us, or to everyone else as well?”
Context
39Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, baálé ilé ìbá mọ wákàtí tí olè yóò wá, òun ìbá máa ṣọ́nà, kì bá tí jẹ́ kí a já wọ inú ilé òun. 40Nítorí náà, kí ẹ̀yin múra pẹ̀lú, nítorí Ọmọ Ènìyàn ń bọ̀ ní wákàtí tí ẹ̀yin kò nírètí.” 41Peteru sì wí pé, “Olúwa, ìwọ pa òwe yìí fún wa, tàbí fún gbogbo ènìyàn?” 42Olúwa sì dáhùn wí pé, “Ta ni olóòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n ìríjú náà, tí olúwa rẹ̀ fi jẹ olórí agbo ilé rẹ̀, láti máa fi ìwọ̀n oúnjẹ wọ́n fún wọn ní àkókò? 43Ìbùkún ni fún ọmọ ọ̀dọ̀ náà, nígbà tí olúwa rẹ̀ bá dé, tí yóò bá a kí ó máa ṣe bẹ́ẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.