Luku 12:36
Luke 12:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ẹ̀yin tìkára yín dàbí ẹni tí ń retí olúwa wọn, nígbà tí òun ó padà ti ibi ìgbéyàwó dé, pé nígbà tí ó bá dé, tí ó sì kànkùn, kí wọn lè ṣí i sílẹ̀ fún un lọ́gán.
Luke 12:36 in English
Luke 12:36 · Berean Standard Bible
Then you will be like servants waiting for their master to return from the wedding banquet, so that when he comes and knocks, they can open the door for him at once.
Context
34Nítorí ní ibi tí ìṣúra yín gbé wà, níbẹ̀ ni ọkàn yín yóò gbé wà pẹ̀lú. 35“Ẹ di àmùrè yín, kí fìtílà yín sì máa jó. 36Kí ẹ̀yin tìkára yín dàbí ẹni tí ń retí olúwa wọn, nígbà tí òun ó padà ti ibi ìgbéyàwó dé, pé nígbà tí ó bá dé, tí ó sì kànkùn, kí wọn lè ṣí i sílẹ̀ fún un lọ́gán. 37Ìbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà nígbà tí olúwa náà bá dé tí yóò bá wọn tí wọn ń ṣọ́nà; lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò di ara rẹ̀ ní àmùrè yóò sì mú wọn jókòó láti jẹun, yóò sì jáde wá láti ṣe ìránṣẹ́ fún wọn. 38Bí olúwa wọn bá sì dé nígbà ìṣọ́ kejì, tàbí tí ó sì dé nígbà ìṣọ́ kẹta, tí ó sì bá wọn bẹ́ẹ̀, ìbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.