Native Bible

Luke 12:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ẹ kíyèsi àwọn lílì bí wọ́n ti ń dàgbà; wọn kì í ṣiṣẹ́, wọn kì í rànwú; ṣùgbọ́n kí èmi wí fún yín, a kò ṣe Solomoni pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ ní gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí.

Luke 12:27 in English

Luke 12:27 · Berean Standard Bible

Consider how the lilies grow: They do not labor or spin.* Yet I tell you, not even Solomon in all his glory was adorned like one of these.

Context

25Ta ni nínú yín nípa àníyàn ṣíṣe tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ọjọ́ ayé rẹ̀? 26Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò ti lè ṣe èyí tí ó kéré bí eléyìí, èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣàníyàn nítorí ìyókù? 27“Ẹ kíyèsi àwọn lílì bí wọ́n ti ń dàgbà; wọn kì í ṣiṣẹ́, wọn kì í rànwú; ṣùgbọ́n kí èmi wí fún yín, a kò ṣe Solomoni pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ ní gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí. 28Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko igbó ní aṣọ tó bẹ́ẹ̀ èyí tí ó wà lónìí, tí a sì gbá a sínú iná lọ́la: mélòó mélòó ni yóò wọ̀ yín láṣọ, ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. 29Kí ẹ má sì ṣe lé ohun tí ẹ ó jẹ, tàbí ohun tí ẹ ó mu, kí ẹ má sì ṣe ṣe àníyàn nínú ọkàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.