Native Bible

Luke 12:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kò sí ohun tí a bò, tí a kì yóò sì fihàn; tàbí tí ó pamọ́, tí a kì yóò mọ̀.

Luke 12:2 in English

Luke 12:2 · Berean Standard Bible

There is nothing concealed that will not be disclosed, and nothing hidden that will not be made known.

Context

1Ó sì ṣe, nígbà tí àìníye ìjọ ènìyàn péjọpọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sísọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ máa ṣọ́ra yín nítorí ìwúkàrà àwọn Farisi tí í ṣe àgàbàgebè. 2Kò sí ohun tí a bò, tí a kì yóò sì fihàn; tàbí tí ó pamọ́, tí a kì yóò mọ̀. 3Nítorí náà ohunkóhun tí ẹ̀yin sọ ní òkùnkùn, ní gbangba ni a ó ti gbọ́ ọ; àti ohun tí ẹ̀yin bá sọ sí etí ní iyàrá, lórí òrùlé ni a ó ti kéde rẹ̀. 4“Èmi sì wí fún yín ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó ń pa ara ènìyàn kú, lẹ́yìn èyí, wọn kò sì ní èyí tí wọ́n lè ṣe mọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.