Luku 12:17
Luke 12:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èmi ó ti ṣe, nítorí tí èmi kò ní ibi tí èmi ó gbé kó èso mi jọ sí.’
Luke 12:17 in English
Luke 12:17 · Berean Standard Bible
So he thought to himself, ‘What shall I do, since I have nowhere to store my crops?’
Context
15Ó sì wí fún wọn pé, “Kíyèsára kí o sì máa ṣọ́ra nítorí ojúkòkòrò: nítorí ìgbésí ayé ènìyàn kò dúró lé ọ̀pọ̀ ohun tí ó ní.” 16Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, “Ilẹ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso. 17Ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èmi ó ti ṣe, nítorí tí èmi kò ní ibi tí èmi ó gbé kó èso mi jọ sí.’ 18“Ó sì wí pé, ‘Èyí ni èmi ó ṣe: èmi ó wó àká mi palẹ̀, èmi ó sì kọ́ èyí tí ó tóbi; níbẹ̀ ni èmi ó gbé to gbogbo èso àti ọrọ̀ mi jọ sí. 19Èmi ó sì wí fún ọkàn mi pé, ọkàn, ìwọ ní ọrọ̀ púpọ̀ tí a tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; sinmi, máa jẹ, máa mu, máa yọ̀.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.