Luku 11:49
Luke 11:49 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí èyí ni ọgbọ́n Ọlọ́run sì ṣe wí pé, ‘Èmi ni ó rán àwọn wòlíì àti àwọn aposteli sí wọn, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí wọn.’
Luke 11:49 in English
Luke 11:49 · Berean Standard Bible
Because of this, the wisdom of God said, ‘I will send them prophets and apostles; some of them they will kill and others they will persecute.’
Context
47“Ègbé ni fún yín, nítorí tí ẹ̀yin kọ́ ibojì àwọn wòlíì, tí àwọn baba yín pa. 48Ǹjẹ́ ẹ̀yin jẹ́ ẹlẹ́rìí, ẹ sì ní inú dídùn sí iṣẹ́ àwọn baba yín, nítorí tí wọn pa wọ́n, ẹ̀yin sì kọ́ ibojì wọn. 49Nítorí èyí ni ọgbọ́n Ọlọ́run sì ṣe wí pé, ‘Èmi ni ó rán àwọn wòlíì àti àwọn aposteli sí wọn, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí wọn.’ 50Kí a lè béèrè ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì gbogbo, tí a ti ta sílẹ̀ láti ìgbà ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, lọ́wọ́ ìran yìí; 51láti ẹ̀jẹ̀ Abeli wá, títí ó sì fi dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah, tí ó ṣègbé láàrín pẹpẹ àti tẹmpili. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín ìran yìí ni yóò ru gbogbo ẹ̀bi àwọn nǹkan wọ̀nyí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.