Luku 11:45
Luke 11:45 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn amòfin dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́, nínú èyí tí ìwọ ń wí yìí ìwọ ń gan àwa pẹ̀lú.”
Luke 11:45 in English
Luke 11:45 · Berean Standard Bible
One of the experts in the law told Him, “Teacher, when You say these things, You insult us as well.”
Context
43“Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisi, àgàbàgebè! Nítorí tí ẹ̀yin fẹ́ ipò ọlá nínú Sinagọgu, àti ìkíni ní ọjà. 44“Ègbé ni fún un yín, *nítorí ẹ̀yin dàbí ibojì tí kò farahàn, tí àwọn ènìyàn sì ń rìn lórí rẹ̀ láìmọ̀.” 45Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn amòfin dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́, nínú èyí tí ìwọ ń wí yìí ìwọ ń gan àwa pẹ̀lú.” 46Ó sì wí pé, “Ègbé ni fún ẹ̀yin amòfin pẹ̀lú, nítorí tí ẹ̀yin di ẹrù tí ó wúwo láti rù lé ènìyàn lórí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin tìkára yín kò jẹ́ fi ìka yín kan ẹrù náà. 47“Ègbé ni fún yín, nítorí tí ẹ̀yin kọ́ ibojì àwọn wòlíì, tí àwọn baba yín pa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.