Luku 11:42
Luke 11:42 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ṣùgbọ́n ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisi, nítorí tí ẹ̀yin a máa san ìdámẹ́wàá minti àti irúgbìn, àti gbogbo ewébẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ ìdájọ́ àti ìfẹ́ Ọlọ́run: wọ̀nyí jẹ́ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe, láìsí fi àwọn ìyókù sílẹ̀ láìṣe.
Luke 11:42 in English
Luke 11:42 · Berean Standard Bible
Woe to you Pharisees! You pay tithes of mint, rue, and every herb, but you disregard justice and the love of God. You should have practiced the latter without neglecting the former.
Context
40Ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹni tí ó ṣe èyí tí ń bẹ lóde, òun kò ha ṣe èyí tí ń bẹ nínú pẹ̀lú? 41Nípa ohun ti inú yin, ki ẹ̀yin kúkú máa ṣe ìtọrẹ àánú nínú ohun tí ẹ̀yin ní, sì kíyèsi i, ohun gbogbo ni ó di mímọ́ fún yín. 42“Ṣùgbọ́n ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisi, nítorí tí ẹ̀yin a máa san ìdámẹ́wàá minti àti irúgbìn, àti gbogbo ewébẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ ìdájọ́ àti ìfẹ́ Ọlọ́run: wọ̀nyí jẹ́ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe, láìsí fi àwọn ìyókù sílẹ̀ láìṣe. 43“Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisi, àgàbàgebè! Nítorí tí ẹ̀yin fẹ́ ipò ọlá nínú Sinagọgu, àti ìkíni ní ọjà. 44“Ègbé ni fún un yín, *nítorí ẹ̀yin dàbí ibojì tí kò farahàn, tí àwọn ènìyàn sì ń rìn lórí rẹ̀ láìmọ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.