Luku 11:27
Luke 11:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, obìnrin kan gbóhùn rẹ̀ sókè nínú ìjọ, ó sì wí fún un pé, “Ìbùkún ni fún inú tí ó bí ọ, àti ọmú tí ìwọ mu!”
Luke 11:27 in English
Luke 11:27 · Berean Standard Bible
As Jesus was saying these things, a woman in the crowd raised her voice and said, “Blessed is the womb that bore You, and blessed are the breasts that nursed You!”
Context
25Nígbà tí ó bá sì dé, tí ó sì rí tí a gbá a, tí a sì ṣe é ní ọ̀ṣọ́. 26Nígbà náà ni yóò lọ, yóò sì mú ẹ̀mí méje mìíràn tí ó burú ju òun tìkára rẹ̀ lọ wá, wọn yóò wọlé, wọn yóò sì máa gbé níbẹ̀, ìgbẹ̀yìn ọkùnrin náà yóò sì burú ju ìṣáájú rẹ̀ lọ.” 27Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, obìnrin kan gbóhùn rẹ̀ sókè nínú ìjọ, ó sì wí fún un pé, “Ìbùkún ni fún inú tí ó bí ọ, àti ọmú tí ìwọ mu!” 28Ṣùgbọ́n òun wí pé, nítòótọ́, kí ó kúkú wí pé, “Ìbùkún ni fún àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì pa á mọ́!” 29Nígbà tí ìjọ ènìyàn sì ṣùjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, “Ìran búburú ni èyí, wọ́n ń wá àmì; a kì yóò sì fi àmì kan fún un bí kò ṣe àmì Jona wòlíì!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.