Native Bible

Luke 11:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nígbà tí alágbára ọkùnrin tí ó ni ìhámọ́ra bá ń ṣọ́ ààfin rẹ̀, ẹrù rẹ̀ yóò wà ní àlàáfíà.

Luke 11:21 in English

Luke 11:21 · Berean Standard Bible

When a strong man, fully armed, guards his house, his possessions are secure.

Context

19Bí ó ba ṣe pé nípa Beelsebulu ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, nípa ta ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde, nítorí náà àwọn ni yóò ṣe onídàájọ́ yín. 20Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe pé nípa ìka ọwọ́ Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ǹjẹ́ ìjọba Ọlọ́run dé bá yín tán. 21“Nígbà tí alágbára ọkùnrin tí ó ni ìhámọ́ra bá ń ṣọ́ ààfin rẹ̀, ẹrù rẹ̀ yóò wà ní àlàáfíà. 22Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹni tí ó ní agbára jù ú bá kọlù ú, tí ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ a gba gbogbo ìhámọ́ra rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé lọ́wọ́ rẹ̀, a sì pín ìkógun rẹ̀. 23“Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, ó lòdì sí mi, ẹni tí kò bá sì bá mi kójọpọ̀, ó fọ́nká.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.