Luku 1:40
Luke 1:40 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì wọ ilé Sekariah lọ ó sì kí Elisabeti.
Luke 1:40 in English
Luke 1:40 · Berean Standard Bible
where she entered the home of Zechariah and greeted Elizabeth.
Context
38Maria sì dáhùn wí pé, “Wò ó ọmọ ọ̀dọ̀ Olúwa; kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.” Angẹli náà sì fi í sílẹ̀ lọ. 39Ní àkókò náà ni Maria sì dìde, ó lọ kánkán sí ilẹ̀ òkè, sí ìlú kan ní Judea; 40Ó sì wọ ilé Sekariah lọ ó sì kí Elisabeti. 41Ó sì ṣe, nígbà tí Elisabeti gbọ́ kíkí Maria, ọlẹ̀ sọ nínú rẹ̀; Elisabeti sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, 42Ó sì ké ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Alábùkún fún ni ìwọ nínú àwọn obìnrin, alábùkún fún sì ni ọmọ tí ìwọ yóò bí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.