Lefitiku 9:6
Leviticus 9:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Mose wí pé, “Ohun tí Olúwa pàṣẹ fún yín láti ṣe nìyìí, kí ògo Olúwa bá à lè farahàn yín.”
Leviticus 9:6 in English
Leviticus 9:6 · Berean Standard Bible
And Moses said, “This is what the LORD has commanded you to do, so that the glory of the LORD may appear to you.”
Context
4àti akọ màlúù kan àti àgbò kan fún ẹbọ àlàáfíà àti ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi òróró pò láti fi rú ẹbọ ní iwájú Olúwa. Nítorí pé Olúwa yóò farahàn yín ní òní.’ ” 5Wọ́n kó gbogbo àwọn nǹkan tí Mose pàṣẹ wá sí iwájú àgọ́ ìpàdé, gbogbo ìjọ ènìyàn sì súnmọ́ tòsí, wọ́n sì dúró níwájú Olúwa. 6Nígbà náà ni Mose wí pé, “Ohun tí Olúwa pàṣẹ fún yín láti ṣe nìyìí, kí ògo Olúwa bá à lè farahàn yín.” 7Mose sọ fún Aaroni pé, “Wá sí ibi pẹpẹ kí o sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti ẹbọ sísun rẹ, kí o sì ṣe ètùtù fún ara rẹ àti fún àwọn ènìyàn; rú ẹbọ ti àwọn ènìyàn náà, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ.” 8Aaroni sì wá sí ibi pẹpẹ, ó pa akọ ọmọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.