Lefitiku 9:19
Leviticus 9:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ọ̀rá akọ màlúù àti àgbò náà: ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, básí ọ̀rá, ọ̀rá kíndìnrín, àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀:
Leviticus 9:19 in English
Leviticus 9:19 · Berean Standard Bible
They also brought the fat portions from the ox and the ram—the fat tail, the fat covering the entrails, the kidneys, and the lobe of the liver—
Context
17Ó tún mu ẹbọ ohun jíjẹ wá, ó bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú rẹ̀, ó sì sun ún lórí pẹpẹ ní àfikún ẹbọ sísun tí àárọ̀. 18Ó pa akọ màlúù àti àgbò bí ẹbọ àlàáfíà fún àwọn ènìyàn. Àwọn ọmọ Aaroni sì mú ẹ̀jẹ̀ ẹran náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì wọn yí pẹpẹ náà ká. 19Ṣùgbọ́n ọ̀rá akọ màlúù àti àgbò náà: ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, básí ọ̀rá, ọ̀rá kíndìnrín, àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀: 20gbogbo rẹ̀ ni wọ́n kó lórí igẹ̀ ẹran náà. Aaroni sì sun ọ̀rá náà lórí pẹpẹ. 21Aaroni fi igẹ̀ àti itan ọ̀tún ẹran náà níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì bí Mose ṣe pa á láṣẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.