Native Bible

Leviticus 8:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ Aaroni, ó fi àmùrè dì í, ó wọ̀ ọ́ ní efodu; aṣọ ìgúnwà, ó sì tún wọ̀ ọ́ ni aṣọ ìlekè oyè àlùfáà tí ó ní ìgbànú tí a ṣe ọnà dáradára sí.

Leviticus 8:7 in English

Leviticus 8:7 · Berean Standard Bible

He put the tunic on Aaron, tied the sash around him, clothed him with the robe, and put the ephod on him. He tied the woven band of the ephod around him and fastened it to him.

Context

5Mose sì sọ fún ìjọ ènìyàn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa ti pàṣẹ pé kí á ṣe.” 6Nígbà náà ni Mose mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá síwájú, ó sì fi omi wẹ̀ wọ́n. 7Ó sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ Aaroni, ó fi àmùrè dì í, ó wọ̀ ọ́ ní efodu; aṣọ ìgúnwà, ó sì tún wọ̀ ọ́ ni aṣọ ìlekè oyè àlùfáà tí ó ní ìgbànú tí a ṣe ọnà dáradára sí. 8Ó fi ìgbàyà sí àyà rẹ̀, ó sì fi Urimu àti Tumimu sí ibi ìgbàyà náà. 9Ó dé e ní fìlà, ó sì fi àwo wúrà tí í ṣe adé mímọ́ síwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.