Lefitiku 8:24
Leviticus 8:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mose sì tún mú àwọn ọmọ Aaroni wá síwájú, ó sì mú ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ ó fi sí etí ọ̀tún wọn, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ yí pẹpẹ náà ká.
Leviticus 8:24 in English
Leviticus 8:24 · Berean Standard Bible
Moses also presented Aaron’s sons and put some of the blood on their right earlobes, on the thumbs of their right hands, and on the big toes of their right feet. Then he sprinkled the blood on all sides of the altar.
Context
22Ó sì mú àgbò kejì wa, èyí ni àgbò ìfinijoyè àlùfáà, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé e lórí. 23Mose sì pa àgbò náà, ó sì mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀, ó tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Aaroni, sórí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti ti ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀. 24Mose sì tún mú àwọn ọmọ Aaroni wá síwájú, ó sì mú ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ ó fi sí etí ọ̀tún wọn, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ yí pẹpẹ náà ká. 25Ó mú ọ̀rá ẹran náà, ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, gbogbo ọ̀rá tó wà lára nǹkan inú àti èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn pẹ̀lú itan ọ̀tún. 26Lẹ́yìn náà ló mú àkàrà aláìwú sí, èyí tó wà níwájú Olúwa àti àkàrà tí a fi òróró ṣe, àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì kó gbogbo rẹ̀ sórí ọ̀rá àti itan ọ̀tún ẹran náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.