Native Bible

Leviticus 8:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn náà ló mú àgbò wá fún ẹbọ sísun Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé orí àgbò náà.

Leviticus 8:18 in English

Leviticus 8:18 · Berean Standard Bible

Then Moses presented the ram for the burnt offering, and Aaron and his sons laid their hands on its head.

Context

16Mose tún mú gbogbo ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú, èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn, ó sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ. 17Ṣùgbọ́n akọ màlúù yìí pẹ̀lú awọ àti ara ẹran àti ìgbẹ́ rẹ̀ ní ó sun lẹ́yìn ibùdó gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti paláṣẹ fún Mose. 18Lẹ́yìn náà ló mú àgbò wá fún ẹbọ sísun Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé orí àgbò náà. 19Mose sì pa àgbò náà, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí pẹpẹ náà ká. 20Ó gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, Mose sì sun orí àti àwọn ègé àti ọ̀rá rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.