Lefitiku 7:5
Leviticus 7:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àlùfáà yóò sun wọ́n lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa. Ẹbọ ẹ̀bi ni.
Leviticus 7:5 in English
Leviticus 7:5 · Berean Standard Bible
The priest shall burn them on the altar as an offering made by fire to the LORD; it is a guilt offering.
Context
3Gbogbo ọ̀rá rẹ̀ ni kí ẹ sun, ọ̀rá ìrù rẹ̀ àti ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú rẹ̀. 4Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lẹ́bàá ìhà rẹ̀, àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ pẹ̀lú àwọn kíndìnrín. 5Àlùfáà yóò sun wọ́n lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa. Ẹbọ ẹ̀bi ni. 6Gbogbo ọkùnrin ní ìdílé àlùfáà ló lè jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́, ó jẹ́ mímọ́ jùlọ. 7“ ‘Òfin yìí kan náà ló wà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi: méjèèjì jẹ́ tí àlùfáà, tó fi wọ́n ṣe ètùtù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.