Lefitiku 7:12
Leviticus 7:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Bí ẹni náà bá gbé e wá gẹ́gẹ́ bí àfihàn ọkàn ọpẹ́, pẹ̀lú ẹbọ ọpẹ́ yìí, ó gbọdọ̀ mú àkàrà aláìwú tí a fi òróró pò wá àti àkàrà aláìwú fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a dà òróró sí àti àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò ṣe.
Leviticus 7:12 in English
Leviticus 7:12 · Berean Standard Bible
If he offers it in thanksgiving, then along with the sacrifice of thanksgiving he shall offer unleavened cakes mixed with olive oil, unleavened wafers coated with oil, and well-kneaded cakes of fine flour mixed with oil.
Context
10Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹbọ ohun jíjẹ yálà a fi òróró pò ó tàbí èyí tó jẹ́ gbígbẹ, wọ́n jẹ́ ti gbogbo ọmọ Aaroni. 11“ ‘Wọ̀nyí ni àwọn ìlànà fún ọrẹ àlàáfíà tí ẹnikẹ́ni bá gbé wá síwájú Olúwa. 12“ ‘Bí ẹni náà bá gbé e wá gẹ́gẹ́ bí àfihàn ọkàn ọpẹ́, pẹ̀lú ẹbọ ọpẹ́ yìí, ó gbọdọ̀ mú àkàrà aláìwú tí a fi òróró pò wá àti àkàrà aláìwú fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a dà òróró sí àti àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò ṣe. 13Pẹ̀lú ọrẹ àlàáfíà rẹ̀, kí ó tún mú àkàrà wíwú wá fún ọpẹ́, 14kí ó mú ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú oríṣìíríṣìí ọrẹ àlàáfíà rẹ wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún Olúwa, ó jẹ́ tí àlùfáà tí ó wọ́n ẹ̀jẹ̀ ọrẹ àlàáfíà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.