Lefitiku 6:20
Leviticus 6:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èyí ni ọrẹ tí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa ní ọjọ́ tí a bá fi òróró yan ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn; ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára fún ẹbọ ohun jíjẹ lójoojúmọ́, ìdajì rẹ̀ ní àárọ̀ àti ìdajì rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́.
Leviticus 6:20 in English
Leviticus 6:20 · Berean Standard Bible
“This is the offering that Aaron and his sons must present to the LORD on the day he is anointed: a tenth of an ephah of fine flour * as a regular grain offering, half of it in the morning and half in the evening.
Context
18Èyíkéyìí nínú àwọn ọmọkùnrin ìran Aaroni ló le jẹ ẹ́. Èyí ni ìpín rẹ tí ó gbọdọ̀ máa ṣe déédé lára àwọn ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa láti ìrandíran. Ohunkóhun tí ó bá kàn án yóò di mímọ́.’ ” 19Olúwa sọ fún Mose pé, 20“Èyí ni ọrẹ tí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa ní ọjọ́ tí a bá fi òróró yan ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn; ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára fún ẹbọ ohun jíjẹ lójoojúmọ́, ìdajì rẹ̀ ní àárọ̀ àti ìdajì rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́. 21Ẹ pèsè rẹ̀ pẹ̀lú òróró nínú àwo fífẹ̀, ẹ pò ó pọ̀ dáradára, kí ẹ sì gbé ọrẹ ohun jíjẹ náà wá ní ègé kéékèèké bí òórùn dídùn sí Olúwa. 22Ọmọkùnrin Aaroni tí yóò rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tí a fi òróró yàn ni yóò rú ẹbọ náà. Ó jẹ́ ìpín ti Olúwa títí láé, wọn sì gbọdọ̀ sun ún pátápátá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.