Lefitiku 5:8
Leviticus 5:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ó kó wọn wá fún àlùfáà tí yóò kọ́kọ́ rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ kí ó yín in lọ́rùn, ṣùgbọ́n kí ó má já orí rẹ̀ tan,
Leviticus 5:8 in English
Leviticus 5:8 · Berean Standard Bible
He is to bring them to the priest, who shall first present the one for the sin offering. He is to twist its head at the front of its neck without severing it;
Context
6àti pé gẹ́gẹ́ bí ìtánràn fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, ó gbọdọ̀ mú wa fún Olúwa, abo àgùntàn tàbí abo ewúrẹ́ láti inú agbo ẹran wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀. 7“ ‘Bí kò bá lágbára àti mú ọ̀dọ́-àgùntàn wá, kí ó mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ìtánràn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀—ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, èkejì fún ẹbọ sísun. 8Kí ó kó wọn wá fún àlùfáà tí yóò kọ́kọ́ rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ kí ó yín in lọ́rùn, ṣùgbọ́n kí ó má já orí rẹ̀ tan, 9kí ó sì wọ́n díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ, ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà ni kí ó ro sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 10Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wá rú ẹbọ sísun gẹ́gẹ́ bí ìlànà, yóò sì ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, a ó sì dáríjì í.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.