Native Bible

Leviticus 5:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Tàbí bí ó bá fọwọ́ kan ohun àìmọ́ ti ènìyàn, ohunkóhun tó lè mú ènìyàn di aláìmọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni náà kò mọ̀, nígbà tí ó bá mọ̀ nípa rẹ̀ yóò jẹ̀bi.

Leviticus 5:3 in English

Leviticus 5:3 · Berean Standard Bible

Or if he touches human uncleanness—anything by which one becomes unclean—even if he is unaware of it, when he realizes it, he is guilty.

Context

1“ ‘Bí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ nítorí pé kò sọ̀rọ̀ nígbà tí a bi í ní gbangba pé kó jẹ́rìí nípa nǹkan tó rí tàbí nǹkan tó mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan, a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù ú. 2“ ‘Tàbí bí ẹnìkan bá fọwọ́ kan ohun tí a kà sí àìmọ́ yálà òkú ẹranko aláìmọ́ tàbí òkú ẹran ọ̀sìn aláìmọ́ tàbí òkú ẹ̀dá yówù tó ń rìn lórí ilẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni náà kò mọ̀, ó ti di aláìmọ́, ó sì ti jẹ̀bi. 3Tàbí bí ó bá fọwọ́ kan ohun àìmọ́ ti ènìyàn, ohunkóhun tó lè mú ènìyàn di aláìmọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni náà kò mọ̀, nígbà tí ó bá mọ̀ nípa rẹ̀ yóò jẹ̀bi. 4Tàbí bí ẹni kan bá búra láti ṣe ohun kan láì ronú lé e lórí, yálà ohun tó dára tàbí ohun búburú, nínú ọ̀rọ̀ yówù tó ti búra láì kíyèsi ara, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò mọ̀ nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kó rí, nígbà tó bá mọ̀ yóò jẹ̀bi. 5Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ̀bi ọ̀kan nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí, ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ irú ọ̀nà tó ti dẹ́ṣẹ̀

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.