Native Bible

Leviticus 4:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ó ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà kí ó sì wọ́n díẹ̀ nínú rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀méje níwájú Olúwa, níwájú aṣọ títa ibi mímọ́.

Leviticus 4:6 in English

Leviticus 4:6 · Berean Standard Bible

The priest is to dip his finger in the blood and sprinkle some of it seven times before the LORD, in front of the veil of the sanctuary.

Context

4Kí ó mú ọ̀dọ́ màlúù wá síwájú Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á níwájú Olúwa. 5Kí àlùfáà tí a fi òróró yàn mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù, kí ó sì gbé e lọ sínú àgọ́ ìpàdé. 6Kí ó ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà kí ó sì wọ́n díẹ̀ nínú rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀méje níwájú Olúwa, níwájú aṣọ títa ibi mímọ́. 7Àlùfáà yóò tún mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ náà sórí ìwo pẹpẹ tùràrí tó wà níwájú Olúwa nínú àgọ́ ìpàdé. Kí ó da gbogbo ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù tókù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ ẹbọ sísun ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 8Kí ó yọ gbogbo ọ̀rá tí ń bẹ nínú akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú àti gbogbo ohun tó so mọ́ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.