Lefitiku 4:27
Leviticus 4:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Bí ènìyàn nínú àwọn ará ìlú bá ṣèèṣì ṣẹ̀ láìmọ̀ tí ó sì ṣe ohun tí kò yẹ sí ọ̀kan nínú àwọn òfin Olúwa, ó jẹ̀bi.
Leviticus 4:27 in English
Leviticus 4:27 · Berean Standard Bible
And if one of the common people sins unintentionally and does what is prohibited by any of the LORD’s commandments, he incurs guilt.
Context
25Lẹ́yìn èyí, kí àlùfáà ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, kí ó fi sí orí ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, kí ó sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. 26Kí ó sun gbogbo ọ̀rá rẹ̀ lórí pẹpẹ bí ó ṣe sun ọ̀rá ọrẹ àlàáfíà. Báyìí ní àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin náà, a ó sì dáríjì í. 27“ ‘Bí ènìyàn nínú àwọn ará ìlú bá ṣèèṣì ṣẹ̀ láìmọ̀ tí ó sì ṣe ohun tí kò yẹ sí ọ̀kan nínú àwọn òfin Olúwa, ó jẹ̀bi. 28Nígbà tí a bá sọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún un, ó gbọdọ̀ mú abo ewúrẹ́ tí kò ní àbùkù wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. 29Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lórí ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, kí ó sì pa á níbi ẹbọ sísun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.