Lefitiku 4:22
Leviticus 4:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Bí olórí kan bá ṣèèṣì ṣẹ̀ láìmọ̀ tí ó sì ṣe ohun tí kò yẹ kí ó ṣe sí ọ̀kan nínú àwọn òfin Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, ó jẹ̀bi.
Leviticus 4:22 in English
Leviticus 4:22 · Berean Standard Bible
When a leader sins unintentionally and does what is prohibited by any of the commandments of the LORD his God, he incurs guilt.
Context
20Kí ó sì ṣe akọ ọmọ màlúù yìí gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣe akọ màlúù tó wà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ṣe ètùtù fún wọn, á ó sì dáríjì wọ́n. 21Lẹ́yìn náà ni yóò sun màlúù yìí lẹ́yìn ibùdó, yóò sì sun ún gẹ́gẹ́ bó ṣe sun màlúù àkọ́kọ́. Èyí ni ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli. 22“ ‘Bí olórí kan bá ṣèèṣì ṣẹ̀ láìmọ̀ tí ó sì ṣe ohun tí kò yẹ kí ó ṣe sí ọ̀kan nínú àwọn òfin Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, ó jẹ̀bi. 23Nígbà tí a bá sì sọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún un, ó gbọdọ̀ mú akọ ewúrẹ́ tí kò ní àbùkù wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ rẹ̀. 24Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lórí ewúrẹ́ náà, kí ó sì pa á níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ sísun níwájú Olúwa. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.