Native Bible

Leviticus 4:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ láìmọ̀, tí ó ṣe ohun tí kò yẹ kó ṣe sí ọ̀kan nínú àwọn òfin Olúwa.

Leviticus 4:2 in English

Leviticus 4:2 · Berean Standard Bible

“Tell the Israelites to do as follows with one who sins unintentionally against any of the LORD’s commandments and does what is forbidden by them:

Context

1Olúwa sọ fún Mose pé, 2“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ láìmọ̀, tí ó ṣe ohun tí kò yẹ kó ṣe sí ọ̀kan nínú àwọn òfin Olúwa. 3“ ‘Bí àlùfáà tí a fi òróró yàn bá ṣẹ̀, tí ó sì mú ẹ̀bi wá sórí àwọn ènìyàn, ó gbọdọ̀ mú ọmọ akọ màlúù tí kò lábùkù wá fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀. 4Kí ó mú ọ̀dọ́ màlúù wá síwájú Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á níwájú Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.